ẸDUN ỌKAN IBARAPA MEJEEJE- Ibarapa Born Panegyrist Sings The Pains Of Ibarapa Land

ẸDUN ỌKAN IBARAPA MEJEEJE

Kiniun Oloola iju motunde
Ijọba ipinlẹ ọyọ mode ooo
Aduragbemi Kiniun Akewi motunde siyin lọrun
Tawọn Ọba wa Nibarapa mejeeje ba dakẹ
N o ni dakẹ
Tori gbogbo ara aja kọ lole gba
Keegun o wọle kaja o ma gbo
Taaba dakẹ tara ẹni n bani dakẹ ni
Ibarapa ẹ tin sun
Walahi ẹ ti sun gbagbe
Tori naa nio jẹ kẹ sọrọ.

Ijọba ipinlẹ ọyọ oo
Latijọ ti mo kuku tin wi
N o ti resin sọrọ mi
N o mọ boya ọrọ mi o ni tunmọ lojẹ ko ri bẹẹ.

Kiniun Akewi
Ilẹkun tio lalugbaja
Ẹni moni ko dẹkun asipaya
Kọmọ tio ni baba yọ ayọpọrọ mọ niwọn
Ọlọrun aanu iwọ nikan latun wo
Dakun mase wo awa ọmọ ibarapa lawo pa
Ọṣẹ ti fulanni n se wa yii o kere
Biwọn tin pani
Ni wọn dani lapa dani lẹsẹ
Bi wọn tin geni lọwọ ni wọn geni lẹsẹ
Se tẹni ti wọn n yibọn fun la fẹ wi
Walahi ninu ibẹru lọmọ ibarapa wa
Bẹẹ sire awọn ijọba wa o sebi ẹni to mọ.

Kiniun Akewi imọ ijinlẹ
Moti dorisa modi sango
Akin nimi tin lakin ẹgbẹ ẹ loju ogun
Pajẹ masẹ lemi Kiniun
Kosi sẹni teegun mi o le ja lọrẹ
Tori mo gboju mo gbonu mosi tun gboya
Baajẹ baa lẹru
Ihalẹ ni fun ru wa
Ijẹ tẹsi jẹ tẹtẹ
Ẹ mase daba dagunro
Toriṣẹ taa firan ikọ ko gbọdọ pakọ
Ẹyẹ tio si dorikodo bi adan osi
Toba dan wo
Yoo tẹnu ṣẹjẹ.

Mr Gomina
Iyẹn gomina ipinlẹ ọyọ
Kini iṣẹ yin nipa eto abo nibarapa
Ninu ewu nla lara ibarapa n gbe
Ninu ibẹru bojo lọmọ ibarapa wa
Ijọba wa ooo
Seb’awa la dibo fun yin
Kilowade tẹo bikita lori aabo Ibarapa pẹlu oke ogun
Ojoojumọ lawọn fulani n jini gbe
Ni ọjọ osu yii
Lawọn fulani tun jinigbe ni ọna Igboora sEruwa
Mọto togbe ero mẹrin
Wọn si gba mọto
Pẹlu gbogbo ero ton bẹ ninu ẹ
Igba totun di ọjọ kẹta
Ọjọ kejilelogun Osu kẹta
Odindi mọto to gbe ero marundinlọgbọn
Ni wọn tun gbe lọna naa
Ẹyin ijọba wa ẹsi gbọ gbogbo eyi
Ẹo sebi ẹni to gbọ
Kiniun Akewi mo mọ pe
Bopẹ boya quary nbọ.

Gbogbo ọba gbogbo ijoye ibarapa
Asiwaju la fiyin se
Dandan kẹ sile kọya fawọn towa lẹyin
Tọba tijoye nibarapa
Kẹya sepade asiko.

IBARAPA YOUTH DECIDES ACT
IBARAPA ONE VOICE
IBARAPA VOICE
IBARAPA OLOFOFO
IBARAPA VOICE ACTIVIST
Ẹ jẹ ya ji kẹ ma sun
Ẹ jin loju oorun
Were toba nijọba lole gba wa
Yoo wulẹ ku’ku gifa
Ka sotitọ Ijọba o raye tiwa
2023 lawọn n wo loke
O wa tasiko ka dide igbenija fun ra wa nibarapa lapapọ.

Hon Debọ Ogundoyin
Oyo State House of Assembly
Wọn n pawọn ọmọ baba yin nibarapa
Ẹ si dakẹ
Ab’odigba togo ibarapa baku tan
Kẹ to maa kọ Condolences letter
Hon Yẹmi Taiwo
Ibarapa House of Representative
Ṣẹ timọ iye ogo ibarapa to ti doku
Motun fẹ kẹ ranti pe Ibarapa lẹ lọ soju loke
Gbogbo oun ta banfẹ
Loyẹ kẹ maa se.

His Excellency aabo lafẹ
Kifọkanbalẹ lewa fun wa
Ki gbogbo ọdọ ibarapa o bale ni ibalẹ aya
Gomina ipinlẹ Ọyọ
Boju o bati fale fale
O yẹ koju o ti ọkọ ọlọmọge
Aya ibarapa mejeeje nja nitori Fulani ika
Awọn OPC tomu Wakili si re lẹwọn
Lai payan
Se tawọn ọmọ meji tiwọn tun ṣẹṣẹ jingbe lafẹ sọ
Mr Gomina ẹ satunse kia kia
Ẹ ma foju kere ọrọ mi
Tori bọja batu tan
Yo kun olori awọn patẹ patẹ
Asi kun awọn agba lọja.

Kiniun Akewi
Mofẹ danu duro na
Moti dabẹ fẹlẹ
Tin geni nibi to tin soge
Mo ti di werepe n o nibi aa gba mu
Ẹni toba fomi ata bọju
Yoo han ara ẹ leemọ
Akọni Ọmọ Ibarapa lemi
Aja tio pa liili o fẹjẹ wẹ
Alaafia Ibarapa losi dun mọmi lọkan.

AARẸ ADURAGBEMI KINIUN AKEWI

If you have anything to say on this, message Kiniun Akewi on WhatsApp: 08116521248

Or on Facebook: Aare Aduragbemi Kiniun Akewi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *